
Àwòrán láti https://fmino.gov.ng/
Láti ọjọ́ 22, Oṣù Igbe, Ọdún 2022 tí Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyemi III ti wàjà ni ìlú Ọ̀yọ́ àti gbogbo ilẹ̀ Yorùbá ti ń fojú sọ́nà fún eni tí yóò gorí àpèrè gẹ́gẹ́ bí Aláàfin Ọ̀yọ́ tuntun. Ní Ọjọ́ Etì, Ọjọ́ 10, Oṣù Sẹẹrẹ ni Gómìnà Ṣeyi Mákindé kéde láti ẹnu Kọmísánnà fọ́rọ̀ ìròyìn rẹ̀ Dọtun Oyelade pé òun ti fọwọ́ sí Ọmọọba Abimbola Akeem Owoade, ọmọ oyè tí àwọn Ọ̀yọ́mèsì fà kalẹ̀.
Wọ̀nyí ni àwọn ohun méje (7) tí ó yẹ kí o mọ̀ nípa Aláàfin tuntun náà
- Ọdún 1978 ni a bíi nínú agboolé Ọwọ́adé-Agùnlóyè ní ìlú Ọ̀yọ́ ni Aláàfin náà.
- Orúkọ bàbá rẹ̀ ni Rasaki Ìbíyọ̀sí Ọ̀wọ́adé tí ó ti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ẹka Ìdàgbàsókè Ètò Ọ̀gbìn ní Ẹkùn Àríwá Ọ̀yọ́ (Oyo North Agricultural Development Programme, ONADEP), tí ó ń ṣèrànlọ́wọ́ láti jáwé sóbì ètò ọ̀gbìn ní agbègbè òkè-ògùn.
- Ọmọ-ọba Akeem kẹ́kọ̀ọ́ parí ní Ilé-Ìwe Girama, Baptist High School, Saki, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ́dún 1992, lẹ́yìn náà ni ó lọ gba Ìwé-ẹ̀rí OND ní Ilé-ẹ̀kọ́ Gbigbonìṣe Ìjọba Àpapọ̀ Ìlaròó láàrin ọdún 1994 sí 1997. Ó tẹ̀síwájú ní Ilé-ẹ̀kọ́ Gbigbonìṣe Ìbàdàn láti gba Ìwé-ẹ̀rí HND nínú Ìmọ̀ Awúrintúnrinrọ (Mechanical Engineering) láàrin ọdún 1999 sí 2001. Lẹ́yìn náà ni ó lọ gba oyè Àkọ́gbà-Fásitì (Bsc) nínú Ìmọ̀ Awúrintúnrinrọ (Mechanical Engineering) yìí kán náà ní Fásitì University of Sunderland àti Oyè Ìkejì-ní-Fásitì nínú ìmọ̀ yìí kan náà.
- Ó sìnrú ìlú gẹ́gẹ́ bí àgùnbánirọ̀ ní Ilé-iṣẹ́ Afẹ́fẹ́ Gáàsì Orílẹ̀-èdè Nàìjííríà, (Nigeria Gas Company) gẹ́gẹ bí ọnímọ̀-ẹ̀rọ lọ́dún 2002.
- Ó ti fìgbà kan ṣisẹ́ rí ní Ilé Ìfowópamọ́ Oceanic Bank International Plc. ní ìlú Warri gẹ́gẹ́ bíi agbowókà láàrin ọdún 2003 sí 2004.
- Ọmọ-ọba Akeem ti ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi Amojúẹ̀rọ Aṣètò (Planning Planning) ní Ilé-iṣẹ́ Oil Reach Company nínú Glasgow, ní ilẹ̀ United Kingdom. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, òun ni Alákòóso Iṣẹ́-Àkànṣe (Project Coordinator) ní ilé-iṣẹ́ Manitoba Hydro, lórílẹ̀-èdè Canada.
- Ẹlẹ́yinjú àánú ni Ọmọ-ọba Akeem, tí ó ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ènìyàn ní abala ètò-ẹ̀kọ́, ìṣẹ́ àkànṣe láàrin àwùjọ àti lásìkò làásìgbò.
